Ajagunna

Ajagunnà gbà wá o!

The Ajagunnà Àgbáyé is an Ògún leadership position conferred by the Ooni of Ife on the recommendation of the Ògún community and the Osògún Àdìmúlà of Ife. The Ajagunnà is the one the Yorùbá people, as a group and individually, run to in times of crisis for solutions. The Ajagunnà leads Yorùbá hunters into battle when just wars need to be fought. The position of Ajagunnà Àgbàyé has been vacant since 1910.

Ọ̀rọ̀ Ṣóki Lóri Oyè Ajagunnà Àgbáyé

Oyè ológun ni oyè Ajagunnà. Àwọn ọdẹ àgbáyé, tí olórìí wọn ń jẹ́ Kábíèsì Oṣògún, ni ó má a ń yàn ẹni tí Ọọ̀ni ó fi jẹ oyè Ajagunnà.Tí àwọn ọmọ ilẹ̀ káàárọ̀-o-ò-jíire ní àpapọ̀ bá fẹ́ ja ogun, Ajagunnà ni jagunjagun tí yó ṣe olóri ogun. Ó ti lé ni igba ọdún tí àwà Yorùbá ti para pọ̀ láti já ogun pẹ̀lú àwọ́n mìíràn. Ẹ ó rántí pé láti bíi 1774 títí di 1880, ara wa ni à ń bá jà! Ògun Ìjàyè, Ogun Kírìjì, Ogun Jálumi, Ogun Èkìtì Parapọ̀, àti bẹ́ẹ lọ, àwà Yorùbá ni à ń bá ara wa jà.Nítorí rògbòdìyàn àwọn Fúlàní darandaran tí o gbòde báyìí, ogun àpapọ̀ ti dé odè o! Ìdí tí oyè Ajagunnà fi ṣe pàtàkì nísiìí nì yẹn o.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé oyè Ògún àti ogun ni oyè yìí, Òrìṣà funfun kán wà tí à ń pè ní “Ajagunnà.” Òrìṣà funfun yìí jẹ mọ́ Ọbàtálá. Òrìṣà Ajagunnà ni a gbọ́dọ̀ bọ tí a bá ń lọ si ojú ogun.